AWIKONKO: Ki le le so
nipa iriri yin lati odun kokanla seyin?
ALAKE:
E se pupo. Iriri mi po repete, meloo ni mo fee so. Sugbon maa tun fee ran yin
leti nipa ti iforowero to mo baa yin se lodun merin seyin. Awon ifowosowopo ti
mo ti n ri gba lati odun mokanla seyin ti po gan, ohun ni mo si le lo so pe o
ti n fi mi lokan bale to si n je ki n maa tesiwaju.
Ohun lo tun n je ki n maa
se daadaa ju ti ateyinwa lo, ki n si maa se awon nnkan ti mo n se lona araoto.
Lara e ni lati maa gba awon omo bibi ilu Egba lamoran nipa mimu idagbasoke ba
ile Egba nipa dida awon ileese nlanla igbalode sile. Bakanna ni amoran lati maa
ri daju pe awon akekoo wa n gbiyanju lati maa se ipo kinni ki won si maa
peregede fun aami eye. Nitori ti won ba wa eko to dara, awon nnkan daradara
miran le tele. O tun n je ki n maa sagbateru awon onise owo ati olokoowo
keekeeke nipa riran won lowo ninu ise onikaluku won, iyen awon omo Egba
lokunrin ati lobinrin.
Lafikun si eyi, a tun ni anfaani lati le je kawon eeyan
wa mo pe awon kan wa ti won nilo iranlowo laarin agbegbe wa, iyen awon to ku
die kaato fun bi awon to ni aisan ropa rose, awon omode ti won o le da se n
nkan funra won, awon odi ati aro, afoju ati aditi atawon mi in ti won wa
lawon igberiko ilu Egba ati beebeeloo. Bakanna ni ti ayeye odun Lisabi
olodoodun ti a maa n se to je pe ileese eto ikansiraeni MTN lo koko sagbateru
odun marun un akoko, ko too di pe ileese GLO naa tun bere sii sagbateru e lati
odun meje seyin, to si n je ki igbelaruge asa wa maa lewaju ninu awon
ayeye asa ti won n se orileede Naijiria. A tun ni ilakaka ti a n se lori oruko
Egba to je pe asiwaju lo n je ninu awon ohun meremere to n sele lorileede yi ti
a si n sise takuntakun lati ma je ki a se ipo keji.
AWIKONKO: E soro nigba
ti e de ori oye nipa isokan awon Oba ile Egba. Nje o te yin lorun bayii atipe
se ife okan yin ti wa si imuse?
ALAKE:
Nkan kii tete te mi lorun nitori pe mo je enikan to le die. A ti sise takun
takun ti o si ti je ki a jere pupo nipa isokan sugbon sibe, ko tii to, a si le
tubo sokan ju bayi lo, a si le mu ki awon nnkan to so wa po dagbasoke si ju
awon nnkan to ya wa lo. Fun idi eyii, ko tii fi be te mi lorun.
AWIKONKO: Ki ni ipo
yin gege bi awon oye Egba kan to je pe awon Oke Ona Egba, Gbagura lo to si.
Bawo le se n se atipe nibo nise de?
ALAKE:
Gege bi eyin naa ti se so pe o ye ki won ti yan won pelu bo se je pe awon
Oke Ona, Gbagura lo nii, Osile ati Agura lo ye ko dahun ibeere yen tori naa, mi
o ni nnkan se pelu nnkan ti kii se ti Egba.
AWIKONKO: Idagbasoke
ilu Abeokuta lati nnkan bi odun meloo kan seyin labe ijoba to wa lode yii, e ti
figba kapn so pe alailegbe ni, sugbon awon ona awon agbegbe kan nilu Abeokuta
ko bojumu. Kini erongba yin lori e?
ALAKE:
Awon ona igboro ni won ti se to je pe o mu ki irin Lafenwa si Ijaiye je iseju
merin. Ti e ba kuro ni Onikolobo ti e n lo si Adatan, laarin iseju mefa, e ti
de Adatan, paapaa soosi ijo Aguda, bakanna lo ri pelu ona to lo lati Mega
Station, Abiola Way, afara oloke, ki e to seju pe, e ti wa ni Asero.
Awon ona yi ma n mu inu didun wa to je pe ti eeyan ba wa lawon ona
adugbo ti ko dara, won o wulo to awon ona igboro, e o le rii ro pupo, inu o
sile baje sii. Igba kan wa to je pe gbogbo ona lo baje patapata. Ki a ni ireti
pe ijoba to ti fi sinu akosile pe won fee se awon ona maa yoo se e gege bi won
se so.
Sugbon lakoko na, e je ki a di idupe han sawon ona ti ijoba ti se han,
pelu awon ona to se pataki,afara oloke to ti yi ilu Abeokuta ka.
E o nilo lati lo silu Ekoo ki a to ri afara oloke, o ti wa nibi, a ro o
pe a le ni opopona to gba oko meta, sugbon sibe, a ti ni won, paapaa ti won tun
se waye fun agbara loto, iyen lawon opopona to se koko naa.
Mo fee fi imo iriri mi han si ijoba Ibikunle Amosun sawon nnkan to ti se
nitori pe iyalenu lo si n je fun mi, ilosiwaju nla lo si n je lero temi tori pe
emi kan na ti mo ti so fun ijoba kan ri pe ki won dogbon sawon ona kan to ti
baje ti won so pe mo ti gbabodi fawon niyii.
AWIKONKO: Ipa wo ni e
n ko lati le je ki awon omo Egba lokunrin ati lobinrin le maa wa sile lati wa
da ile ise sile?
ALAKE:
Opo awon ileese to wa nipinle Ogun lo je pe abe Egba ni won wa. O da mi loju pe
e mo ibi ti Egba tan de lo je ki e bere ibeere yen. Ti e ba ri mi ni koko, maa
so o fun yin. A nilo lati maa dupe lowo Olorun fun awon nnkan ti a ni.
AWIKONKO: Igbagbo opo
eeyan nipe pataki ayeye odun Lisabi ni lati mu isokan wa laarin awon ara Egba.
Gege bi Oba alaye ile Egba, bawo le se le sapejuwe ayeye yii?
ALAKE:
Gege bi eyon maa ti gbe ninu ibeeee yin pe nitori isokan ni a se n se ayeye
odun Lisabi ti o si n mu ki a maa lo kaakiri igun merin Egba lodoodun, mo
gbagbo pe a ti se aseyori nla nipa ayeye yii atipe ko tii tan sibe, a si n sise
si.
Ni ti odun yi, a ni lero lati lo si igbo Lisabi lojobo Tosde lati le je
ki aaye gba wa daadaa.
AWIKONKO: O fee dabi
eni pe awuyewuye wa lori oro Jaguna Egba, se o si wa atipe bawo ni ipo lowo
bayii nile Egba?
ALAKE:
Maa tun da yin pada si Iran Egba latigba ti a ti tedo silu Abeokuta lodun 1830.
Ti e ba lo ye e wo, yoo yi ero okan yin pada si ibeere ti e bere yen.
AWIKONKO: Awuyewuye ti
n wa laarin awon Egba ati Ibarapa, ojo ti pe. Awon Ibara gbagbo pe awon lawon
koko tedo, awon kan ni Ijemo lo ni Egba. Ipa wo le n ko lati le je ki isokan wa
laarin awon mejeeji?
ALAKE:
E mi o ro bi e se n ro yen pe won lawon lawon ni Egba, paapaa julo Alaga ijoba
ibile guusu Abeokuta nigba ti won yan mi gege bi Alake nigba yen je omo Ibara,
gbogbo omo Egba ni won ni eto si ofiisi nigba maa.
A o lo be eeyan kan pe oun lo ni eleyi tabi toun. Eyokan ni wa. Eje ki n
je ko yee yin pe lati Odo Ogun to koju si Ago Ina lo de eti Oyo, awon Egba lo
poju ni Awe. Awon Ibara wa ni Orile Ibara, a o soda odo lo sodikeji. Awon Ijemo
lo wa nibi ati Itoko nigba tawon Egba to ku wa darapo mo won. Nigba yen ni won
so pe ki won wa bu iyepe ibi ti won fee tedo si, won o nilo lati ja ki won to
bu iyepe maa, won o nilo lati paayan, awon nikan ni won wa nibe nigba ti won
debi, ina ti won ri, odo Ijemo ni won ti ri.
A ni opo eeyan to je pe iro ni won
n pa to ba ka pa Iran fawon eeyan,idi ni yi ti won fi yo kuro nile eko girama,
inu awon kan n dun pe won yo kuro nitori pe awon kan fi aaye sile lati maa pa
iro awon nnkan ti ko ni eri aridaju. Nkan ti mo le so ni yen.
AWIKONKO: Ki le fee so
nipa ikobinrin jo nko?
ALAKE: Mi o ri nkan to le yi ero okan mi pada bi bee ko, ee
ti gbo le Alake ti fe iyawo miran. Mi o ki n se eni to n bo oro bi awon to ku.
Mo feran obinrin ju bee lo sugbon mo feran ifokanbale pupo, nnkan to je ki n
yato sawon to ku niyen. Alaafia ati ibale okan je mi logun pupo ju ikobinrin jo
lo, e ma gbagbe pe idile oniyawo pupo ni mo ti jade wa, tori maa mo ti aimoye
eyi yo da ati eyi to ku die kaa to ninu e. Fun idi eyi, e o le da mi lebi lori
eyi ti mo fowo mu.
No comments:
Post a Comment