Desmond |
Bo tile je pe bi ala lo si n je fokunrin naa ti won sese
dibo yan gege bi Aare egbe sorosoro to daduro lorileede Naijiria, iyen
Freelance Broadcasters’ Association of Nigeria, FIBAN lori bo se yege nibi eto
idibo to koja.
Desmond Abiodun Nwachukwu lokunrin naa, eni to je alaga ana
fegbe naa nipinle Ogun. Gege bii iwadii ti AWIKONKO se, a gbo pe, ko too di pe won
seto idibo naa lojobo Tosde ose to koja lo ti nn kaakiri odo awon agbaagba ninu
egbe naa, to si n salaye idi to fi fee dupo aare egbe naa.
Latigba naa ni a gbo pe won ti n fun ni amoran lori igbese to
le gbe lati rii pe o depo naa pelu iranlowo awon oludibo. Sugbon nigba ti
ipolongo idibo naa bere ni pereu lose bii meji seyin lara e ko ti bale mo.
Ohun taa gbo nipe, okunrin naa, iyen Desmond ko lee sun
oorun wakati meta lale, ironu bi aare egbe naa yoo se tee lowolo n ro. Awon kan to
sunmo daadaa je ko ye wa pe, okunrin naa di afadura-jagun ojiji lori ko le depo
naa.
Won ni bi Desmond se n gbadura kira-kira, bee lawon pasito
atawon aafa lorisiri naa ko dawo adura duro lori aseyori Desmond gege bi Aare
egbe naa, titi di ojo idibo ku ola ni won fi n gbadura. Bakanna la tun gbo pe
inu aawe biribiri lokunrin naa wa.
Lojobo Tosde ose to koja ti idibo naa waye nilu Ibadan, nibi
tawon agbaagba egbe naa ti pe jo pelu awon oludibo ati ajo eleto-idibo egbe naa, tawon
eeyan lorisiri naa si wa nikale lati mo eni ti yoo jawe olubori laarin awon
meji to n dupo naa.
Nigba tidibo naa bere, gege bi ohun ti a gbo lati enu awon
to n sakiyesi okunrin naa, won ni se lo n gbadura kikan-kina sinu pe ki Olorun
gbakoso, nitori pe awon ipinu rere toun ni fun idagbasoke ati ilosiwaju egbe
naa, asiko yi loun fe koo wa si imuse.
Sugbon nigba ti ajo eleto idibo naa bere sii ka ibo naa,
oruko Desmond lo poju ninu oruko ti won n da, nibe lawon kan ti bere sii bo
lowo pe o ku oriire. Leyin-o-reyin ni won rii pe ibo mokanlelaadorin (71votes)
ni Desmond ni, ti enikeji ti won jo n dije si ni ibo metadinlogbon(27).
Loju ese ni won so pe Yemi Sonde, Jigan Akala to je Aare
egbe naa ti so pe, kawon omo egbe naa bere sii dari gbogbo oro to ba niise pelu
egbe naa si Desmond, ki wahala le kuro lorun oun.
Gbara ti won kede Desmond gege bi eni to jawe olubori lawon
ololufee ti gbee soke, lati baa sajoyo naa.
No comments:
Post a Comment