Onarebu
Oladipupo Adebutu, to je okan lara awon omo ile igbimo asofin agba nilu Abuja,
to tun je alaga igbimo to n ri soro idagbasoke awon agbegbe lorileede Naijiria
ti so pe oun ko darapo mo egbe oselu All Progresseives Congress, APC.
Adebutu so
pe aheso ti ko lese nile niroyin ti won n gbe kaakiri ori ero ayelujara wipe oun
ti darapo mo egbe oselu APC. O ni ko si nnkan to jo bee, ati pe ki lo fee gbe
oun denu egbe oselu naa.
AWIKONKO
gbo ninu atejade ti Arole Afeez Bello, eni to sunmo Adebutu fi sita lati fi
tako oro naa, lo ti so pe kawon eeyan dekun lati maa gbe iroyin ti ko lese nile
kaakiri.
O ni “A ti
atejade gba pe iroyin kan nlo kaakiri ori ero ayelujara intaneeti pe Onarebu
Oladipupo Adebutu ti loo darapo mo egbe oselu APC. Fun aridaju awon to n siye
meji lori iroyin naa, paapa julo awon ololufee wa ti won fee maa gba iroyin naa
gbo. Iro patapata gbaa ni iroyin naa, ko si otito kan nibe, imo awon alatako ni
iroyin naa.”
O so pe ko
seese ki Adebutu to wole labe egbe oselu Peoples Democratic Party, PDP, lo maa
wa ronu lati salo sinu egbe oselu PDP. O ni aaye sile foun lati darapo mo egbe
oselu naa lakoko idibo, sugbon toun ko lo lo anfaani naa.
O ni se
lakoko ti egbe oselu APC ko mo nnkan ti won n se mo, ti ijoba ti won n se ko ye
won mo loun yoo sese wa lo darapo mo won.
O war o
awon araalu lati ma se gba iroyin naa gbo nitori pe awon ti won ko fe ilosiwaju
foun ni won n gbe iroyin naa kaakiri.
No comments:
Post a Comment