Gomina ana nipinle Ogun, Otunba Gbenga Daniel ti gba ijoba orileede
lamoran pe ki won je ki idagbasoke orileede yi je won logun ju ohunkohun lo
lati le fi okan awon omo orileede ninu eto oro aje to denu kole.
Daniel soro yi lakoko to n ki awon araalu fun ti ajoyo odun tuntun ti a
sese bo si yi nibe lo ti so pe ki ijoba lapapo, iyen ijoba ibile, ipinle ati
ijoba apapo je ji idagbasoke je won logun ninu odun tuntun ti a sese bi si yi
nitori pe ohun ti o se pataki julo niyen lakoko risesan yi.
O so pe awon idagbasoke bii ohun elo amusoro, ina, pipese ise fawon odo,
ise agbeje, eto ilera, eto eko to see foju ri, awon ileese igbalode atawon mi
in ti won se pataki lati mu ki idagbasoke de ba ilu ti o si le mu ayipada rere
bawon eeyan orileede yii lapapo.
Otunba Daniel tun so pe awon nnkan amusoro ti Olorun fi ta wa lore
lorileede yii je awon ohun amuyangan ti o to lati yi eto oro aje to denu kole
yii si rere lai fi ti risesan ti a n pariwo yi se. O ni anfaani lawon nnkan naa
je fun wa lati maa wo won gege ohun elo idagbasoke.
Bakanna lo gbawon araalu naa lamoran pe ki won maa se ohun gbogbo
niwontunwonsi, ki won si ma se aseju ninu ohun ti won ba n dawole. Bee lo so pe
kawon naa ri daju pe won n fowosowopo pelu ijoba nipa gbigba ladura si Olorun
lati fun wa ni awon adari otooto ti won yoo sise won gege bi ise.
No comments:
Post a Comment