Buhari lakoko to n wo oko baluu |
Aare
orileede Naijiria, Ogagun Muhammed Buhari lojobo Tosde ana ti kuro lorileede
yii lati lo gba itoju to peye ni orileede United Kingdom, iyen ti won so pe
isinmi olojo die ni Baba lo fun un.
Be o ba
gbagbe pe laipe yi ni Buhari so pe, o ye kawon senato atawon oloriile igbimo
asofin agba lo fun isinmi olojo mewaa lati lo gba itoju, ki won si le ni ilera
pipe lati maa fi sise ti won yan won fun.
Ninu
atejade ti Akowe agba e, Ogbeni Femi Adesina fi sita lo ti so pe isinmi olojo
rampe ni Aare Buhari lo fun, lati se ayewo ilera ara e.
O so pe, bo
tile je pe ojo Aje Monde ose to m bo ni won maa bere sii ka ojo fun Aare, ojo
kefa osu to m bo ni Buhari maa pada sorileede Naijiria lati le tesiwaju ninu
ise ilu.
AWIKONKO
gbo pe, ki Aare Buhari to forileede sile lo ti fa ise le igbakeji e, Ojogbon
Yemi Osinbajo lowo pe ko maa tuko orileede titi di asiko toun fi maa pada de
sorileede lati tesiwaju ise oun.
Bo tile je
pe orileede Switzerland ni igbakeji naa wa nibi to ti n lewaju awon iko tijoba
apapo yan nibi eto oro aje orileede lagbaye, oni ojo Eti Fraide ni AWIKONKO gbo
pe Osinbajo maa de sorileede Naijiria.
No comments:
Post a Comment