Kii se
akoko ree ti Gomina ipinle Ekiti, Ogbeni Ayodele Fayose maa bu enu ate lu
isejoba Buhari pelu bi nkan se le koko fawon araalu to si je pe se lopo awon
araalu n tiraka lati rowo mu lo senu.
Gomina naa
so pe awon omo orileede Naijiria ko nilo idanilekoo kankan mo lati ma se gba
egbe oselu APC laye mo ninu idibo apapo to n bo lodun 2019 eyi to seese ki Aare
Buhari so pe oun fee se eleekeji.
Gege bo se
so, o ni ko seni to le won alaafo to wa laarin ijoba ti Aare ana, Omowe
Goodluck Jonathan se ati eyi ti Aare Buhari n se lowo yii nipa idagbasoke. O ni
igimu jina soro.
Gomina
Fayose soro yi lakoko to n bawon oniroyin soro nipinle naa. Ninu atejade ti oga
agba leka iroyin fun gomina, Ogbeni Adelusi Idowu fi sita, o so pe ibanuje nla
lo je pe ijoba odun meji egbe oselu APC labe Buhari ti mu ki igbe aye le koko
mo awon araalu kaka ki n de fun won.
"Naijiria
ti a lala ri yato si nkan ti a ri bayii. Awon nkan ti mo so nipa Aare Buhari ti
n wa si imuse. Ki akoko idibo too de, mo so pe kawon eeyan ma dibo fun un. Ebi
n pawon omo Naijiria, won si ti n kabamo. Bi eni ti ko jamo nkan ba dije pelu
Buhari lodun 2019, Buhari yoo fidi Remo. Awon omo Naijiria ko nilo idanilekoo
mo lati mo pe ko ye ki won dibo fun Buhari mo lodun 2019. O ti doju han
gbangba.
"Opo
awon to dibo fun un to fi wole ni won ko mo eeyan to je nitori pe won sese n pe
omo ogoji odun ni, awon to je pe omo owo ni won si je nigba to se ijoba Olorun
lodun 80s. Aladase nijoba e atipe yato si pe o ti isejoba ri lakoko ologun, ko
ni awon amuye lati dari orileede yii. Tunde Idiagbon lo baa sejoba lodun naa
lohun.
"Ko
kaju osuwon rara. E o le fi we Aare ana, Goodluck Jonathan. Jonathan gba
ijakule nibi idibo to sagbateru e." Fayose
No comments:
Post a Comment