Awon olopaa ipinle Ogun ti gboro mo awon omo egbe okunkun lowo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, January 18, 2017

Awon olopaa ipinle Ogun ti gboro mo awon omo egbe okunkun lowo

Ose to koja yii kii se ose to dara fawon omo egbe okunkun nipinle Ogun nitori bawon olopaa se yari peluu won, titi di akoko ti a si n ko iroyin yii lowo, metadinlogbon lowo tit e ninu won ti won si n je igbadun lowo logba Eleweran niluu Abeokuta.

Gege bi a se gbo, awon bii mewaa lowo koko te lojo Isegun Tusde ose to koja lakoko tawon eeyan naa n koju ija sira won niluu Mowee nijioba ibile Obafemi Owode.

Nibi ija naa niroyin ti je ka mo pe won ti pa okan lara won, bawon olopaa si se de bee lawon eeyan naa ti fonka, eyi to mu kawon olopaa maa sawon kaakiri.

AWIKONKO gbo pe Omobinrin kan wa lara awon towo te, eyi ti won so pe oun lo saaju awon to n bara wonnja lojo naa.

Ki i se Mowe ni won  lawon omo egbe okunkun naa ti wa, won ni won kan fi adugbo naa sebudo ogun ti won ti pade lati le mo agba.Gege bi awon toro naa soju se wi, lojiji ni won so pe awo n gbo iro tawon eeyan si n sa asala femi won.Ko to di pe won pea won olopaa.

Bakan ewe,awon metadinlogun omo egbe okunku min in lowo tun te lojooru Wesde ose to koja niluu Ijebu Igbo, Won ni se lawon araadugbo tawon olopaa lolobo pea won odo kan wa tise won ko mo, ti wonm si n da adugbo laamu.

Loju ese lawon olopaa ti loo sibe ti won si ko awon eeyan naa, agbegbe merim otooto ni won so pe owo tit e awon eeyan naa. Lara awon nnkan ti won ri gba lowo won ni ibon ilewo, igbo ti won  n mu, obe atawon nnkan oloro min in.

Nigba to n soro nipa isele naa, Ogbeni Abimbola Oyeyemi to je agbenuso fawon olopaa nipinle Ogun so pe kayeefi nisele naa si n je fawon nitori pe bawon se n fonrere to pe kawon omo egbe okunkun lo towo won bo aso, bee ni won ko gbo.

O so pe opo moto onimoto ni baje ti won si mu ile aye su awon eeyan agbegbe naa lojo naa nitori ko seni to no ibi to le gba lati sa asala femi ara e lakoko tawon omo egbe okunkun naa doju ija ko ara won.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI