Oni je ojo
malegbagbe ninu aye Arabinrin kan, to je okan lara awon asiwaju obinrin to
feran lati maa gbe Asa ati Ede Yoruba laruge, Adejoke Sharon Somoye, topo mo si
Adejoke Ewa Ede.
Bo tile je
pe lati nnkan bi ojo meji seyin lomobinrin naa ti n fi awon aworan ara e sori
ero ayelujara bii Facebook, Instagram, Twitter, Whatsapp lati fi ki ara e ku
ayeye ojo ibi, paapaa lati fi dupe lowo Olorun fun ibi to wa lonii, sibe
AWIKONKO ko nii fa seyin lati ki gbajugbaja sorosoro naa ku oriire ayeye ojo
ibi e.
Bee ba
gbagbe pe losu kokanla odun to koja ni Adejoke Ewa Ede se ayajo ayeye Ewa Ede
olodoodun to ma n se lati fig be Asa ati Ede Yoruba laruge, nibi ti awon
agbaagba leka Oselu, nidi ise ijoba, atawon ojogbon to mo nipa Ede Yoruba
paapaa awon Asa ati Ise ile Adulawo ti peju sibe.
Bo tile je
pe inu e ko fi bee dun si bi ayeye naa se lo lojo naa, nitori tawon Oba Alaye
meji, iyen Alaafin Oyo, Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi ati Alake tile Egba, Oba
Michael Aremu Gbadebo ti ko yoju ati awon eeyan jankan-jankan to ti fi iwe pe,
sugbon ti won ko yoju lojo naa, sibe, o dupe lowo Olorun Aseda pe ipinu oun wa
si imuse lojo naa.
Nibi ayeye
naa ni Oba Orin, Saheed Osupa ti dalu bole fawon ololufee atawon alejo. Awon
Obaye ko gbeyin nibi ayeye lojo naa.
Eni to ba
ri Adejoke Ewa Ede, ko ba wa kii ku oriire ayeye ojo ibi e todun yii, ti a si n
gba ladura pe, yoo se opo odun laye ati laaye rere ninu alaafia ati ifokanbale.
No comments:
Post a Comment